menu-iconlogo
huatong
huatong
bantu-jagun-jagun-cover-image

Jagun Jagun

Bantuhuatong
shani1sthuatong
Lyrics
Recordings
Jagun-jagun ló ń bọ̀

Jagun-jagun ló ń bọ̀

Jagun-jagun ló ń bọ̀

Olórí-ogun ò gbọdọ̀ kẹ́yìn ogun

Ọ̀kan ṣoṣo Ẹja tí ń d'abú-omi rú

Ọ̀kan ṣoṣo Ẹfọ̀n tí ń d'ọ̀dàn rú

Ọ̀kan ṣoṣo Àjànàkú tí ń m'igbó kìji-kìji

Jagun-jagun dé, ọmọ ọba kìí jagun bí ẹrú

Òlọ́ṣọmọ́dìí gba ìbọn lọ́wọ́ ọmọ ojo

Jagun-jagun, afiwájúgbọta, afẹ̀yìngbọfà

Jagun-jagun ò fẹ́rọ̀, alágbára èyàn tí ń fi májèlé ròfọ́

Àlùjànú èyàn tí ń fi ọmọ-odó tayín

Bó ṣe ń bá ọmọdé ṣe, bẹ́ẹ̀ ló ń bágbà ṣe

Kọ̀nàn-kọ̀nàn já tòun tòwú

Jagun-aso, ẹkùn ọkọ òkè!

Arọnimaja ṣáagun!

Ó ṣáagun ṣáagun, ó ṣáagun títí

Ohun l'awo Alágbàá'a, èyí tí ó fi ta b'aṣeégún lójú

Jagun-jagun ló ń bọ̀

Jagun-jagun ló ń bọ̀

Jagun-jagun ló ń bọ̀

More From Bantu

See alllogo