menu-iconlogo
huatong
huatong
avatar

Adura Ololufe

Sola Allysonhuatong
englesaqjoehuatong
Lyrics
Recordings
Adura mogba fun e ololufe mi

Ire ni mo n su fun e ayanfe oko mi ore mi

Oo ni kagbako l'aye oo ni r'ogun akoba

Oo ni s'irin l'aye be oo ni t'oju ile mole

Ainif'okanbale o ni y'odo re lailailailailai

Oo ni m'osi l'aye, aye re a ma dara si

Ife eledumare ree e ooo ore mi

O fewa fun re, o fewa f'ayo taa ba barawa s'otito

Angeli alayo mi faramo tire nse ni won njo s'ise

Iranse alaanu re wa pelu t'emi nwon njo rin po ni

Ibaase 'wo layo pupo latagbala eledumare wa inu oluwa aa dun si

Ibaase' wo layo pupo latagbala

eledumare wa o, inu oluwa aa dun si wa

Oba ni a lowo a bi'mo

Oba ni a s'owo a j'ere

Oba ni a r'aje jeun

Imole aa ma tan si

Imoran mi ree fun e ooo oloro mi

Imoran ni mo n gba e ninu ife to jin oloro mi maa gbo

Pe ko maa s'ora se, ore mi at'orun s'ora se

Jowo f'arabale ko gb'emi olorun l'aye ko

m'okan at'eti re kuro ninu etan to kun'nu aye

Gbogbo ohun to ma n dan ko ni wura,

joo ma fi ididi w'ola, ola aa to ni wa,

Fitila ona re o ni ku lailai, aye re a ma dara si.

Owo o ni wan n'ile wa

Owo Olorun nbe lara wa

Owo Oluwa nba wa lo

Imole a ma tan si

Ope ti mo nda l'ojojumo ree ore okan t'eledua fun mi maa gbo

Modupe mo yin'le f'olu to gbe mi pade alaanu

Mosope mi o kuta l'oju oja ife, eleda lo ba mi se

Alabarin t'eledua yan fun o gangan ni moje

Alabase t'olorun fifun mi gangan ni iwo je

Ajose wa a maa mayo wa o nfun wa l'ayo,

ka sa maa sora se Ajose wa a maa mayo wa, ka sa maa sora se

Oba ni a lowo a bi'mo

Oba ni a s'owo a j'ere

Oba ni a r'aje jeun

Imole aa ma tan si

Ife okan mi ree, ore okan mi tipetipe maa gbo

Pe ka je imole, imole wa ko tan f'araye ri

Ka f'ara wa lowo, ka jo rin f'olu, ka nipa rere f'ayo

Eni waye lai mu'fe orun se, asan bansa

Aa r'owo lo, aa f'ola we, ka s'ise taa ran wa wa pa bi fun

Ajose wa a maa mayo wa o nfun wa l'ayo, ka sa maa sora se

Ajose wa a maa mayo wa, ka sa maa sora se.

Ajose wa a maa mayo wa...

Ka sa maa sora se...

More From Sola Allyson

See alllogo