menu-iconlogo
huatong
huatong
avatar

Igbagbo

Sola Allysonhuatong
mookie71040huatong
Testi
Registrazioni
Igba miran o ma n se mi bii ki n pada seyin

Igba miran o ma n se mi bii ki n jowo Re

Igba ti 'ji aye ba n ja, bii ki n pada seyin

Igba t'okan mi poruru, bii ki n jowo Re

Sugbon mo mo, Iwo ni Eni ti kii ko ni sile

Bee ni mo mo, Iwo ni Eni to s'olododo

Sugbon mo gba, Iwo ni Eni ti kii ko ni sile

Bee ni mo gba, Iwo ni Eni to s'olododo

Igbagbo mi duro lori ododo Re

Iwo lapata ayeraye, ibi isadi mi

B'okan mi poruru, ko le p'ase Re da lailai

Iwo s'olododo, mo si mo O ni Alaanu

Igbagbo mi ro mo O, Iwo ni agbara mi

Oke ni mo f'okan si, ibi ti iranwo gbe wa

Fun mi lokun atoke wa, ki n mase pada seyin

Ki n ma sise ninu iriri, ki n mase jowo Re

Tori mo mo, Iwo ni Eni ti kii ko ni sile

Bee ni mo mo, Iwo ni Eni to s'olododo

Tori mo gba, Iwo ni Eni ti kii ko ni sile

Bee ni mo gba, Iwo ni Eni to s'olododo

Iriri aye a maa fe so 'yan d'eni o ni 'gbagbo

Sibe mi o gbeke l'ohun kan leyin agbara Re

Ogbon ori eeyan o le roo ja, eto too ni lailai

Koda b'okan mi se 'yemeji, ileri too se o duro

Abrahamu, Serah, won rerin looto ntori o dabi pe yeye ni

Sibe won d'eni itokasi fun ibukun pipe

Fun mi lokun atoke wa, Iwo ni Alatileyin

Ki n ma subu, ki n la ajo yi ja, ki n mase jowo Re

Tori mo mo, Iwo ni Eni ti kii ko ni sile

Bee ni mo mo, Iwo ni Eni to s'olododo

Tori mo gba, Iwo ni Eni ti kii ko ni sile

Bee ni mo gba, Iwo ni Eni to s'olododo

Mo mo daju Iwo ni Eni ti kii ko ni sile

Bee ni mo gba, Iwo ni Eni to s'olododo

Tori mo mo, Iwo ni Eni ti kii ko ni sile

Bee ni mo gba, Iwo ni Eni to s'olododo

Altro da Sola Allyson

Guarda Tuttologo